ORI-BIBO.. (APPEASE YOUR CREATURE)

 

Kini Anpeni Ori (Head)  Gangan


Ori ni oba ara, ori yi ni oje engine to n control ara wa, ori lo npase bi ara sema lo isemi, ti ori bati baje.. Gbogbo eya (part) ara toku na ko wulo ma... Ori je asiwaju tori ohun ni olohun fise olutosona eda nile aiye...ti ori eni bagba abode, isemi eniyan yen mawa ninu wahala ati idamun ni.. 

 Tori re ni agbodo fi mojuto eleda wa tabi iseda wa, tori re ni awon baba wa fi pataki ori.. 

Awon baba wa amaso pe (ori ni apesin, ori ni gbani, orimi matakomi, orimi magba abode) 

Adura ti awon baba wa ma nse Nipa ori kise kekere tori iseda eniyan se pataki ninu aiye.. 


KINI ANPENI ORI BIBO.. 


Ori bibo je ona ti awon baba wa ma ngba lati lefi be ori (head)  tabi se etutu ori.. Ni asiko ti nkan bale ma eda, ti atije ati mu ba nira tabi ti orire ba gba abode.. 

Opolopo eniyan ni ori re le pupo, tosi ye kioma bo orire lorekore tori iseda re le, sugbon opolopo eniyan koma iru iseda ti ohun nlo debi toma mape oye ki ohun mabo ori ohun.... 

Kise gbogbo eniyan ni asasi tabi ogun awon ota nda laamu... Bikisepe ori re lo nbaja. 

Bi eda base awon nkan totako kadara re, odidandan ki orire tako.. 


ASIRI WO LOWA LABE ORI BIBO..  

Ori bibo je nkan tose pataki fun opolopo eniyan.. 

Eda toba ni ogun ota pupo, toba bo ori re tosi se ise igbinyaju lati segun ota, orire maba segun lasiko tori iseda re ma wa pelu re lati segun.. 

Eniyan ti ori ba ntako... Koda ti oba nse ise igbinyaju lati ri owo tabi nkan miran... Koni sise lara re tori iseda re ntako lowo, gbogbo nkan to ba ndawo le koni rojutu re tori ori to je asiwaju isemi re gan kosise fun ma.. 

Awon ota ama gba abode fun iseda eniyan tiwon koba ri aburu kankan se fun eniyan, ori elomi wa leyin re dada tojepe tiwon base asasi kan si, koni ran rara.. Tori idi eyi ni awon ika eniyan fima gba abode fun ori elomi... 

Won ma pe ti ori re bati gbabode kole ri onalo laiye re, gbogbo igbinyaju re lati la laiye koni bosi.. 

Ti olohun basetan lati mu alagbara aiye to nfi agbara re ba aiye awon eniyan je, orire magba abode tiosi sisé... Asiko yen ni awon agbara yen koni je larare ma.... 

Olohun tida eniyan kokan pelu ori tie pelu kadara ti ori na ngbe bowa si aiye.. Tori kadara oni kaluku ototo nih.. 

Ona ti ori onikaluku yiose gba sise ototo ni, oni kaluku pelu ori tie, ori lemagbe iwo, ki ori sima tako elomiran.. Gbogbo re loni idi (reasons) 


BAWO NI ASE MA NBO ORI... 


Awon eniyan kan tie ni kosi nkan to nje ori bibo, sugbon koyewon ni... Olohun toda eniyan  pelu kadara re tosi ni ki ori mase akoso kadara yen.. 

Se olohun koma nkan to nse? 

Ojo ti obati de ile aiye gege bi omo tuntun ni oti kue ku eleda re... Bobase wu e kio se igbese aiye re tori olohun tipari oro aiye re si ori (head) re 

Gbogbo nkan ti eniyan maje laiye yi ori eni nani yio gbe e debe, aditu eledumare ni Eleyi je.. Tori olohun lo npase gbogbo re, ositi fi ori pari ise ti eniyan nbowa si aiye waje .. 

Ojo ti eniyan bade ile aiye ni olohun tise eto awon spirits tio ma ba eniyan sise (spiritually)... Tori re ni akogbodo fise awon nkan totako irawo ati akosejaiye wa... Tori awon spirits yi ni nkan tiwon feran besi ni won ni awon nkan ti wonkonifesi.. Tori re ni oro aiye elomiran fima daru leyin toba se nkan totako kadara re.... 


Olohun ni oba toni gbogbo re... Labe agbara ati ase olohun nani gbogbo re wa.. Sugbon eda tikoba fi olohun sile olohun maba to oro aiye re lona tio rolorun, lopin igbati ohun na kobati wo oro aiye arare niran.... 


ORI BIBO YI WA LORISIRISI 

gbogbo eniyan loni awon nkan toba kadara re mu lati lefi bo orire... Tori re ni afi ma nse iwadi lati lema nkan toba irawo kokan mun tabi iseda kokan mu lati bo orire... 

Awon baba wa ma nso wipe ori laba mabo abafi orisa sile, ori lo ngbe eni, ori lo nla eni, ogun loni ojokan ipanju ori eni loni Ojo gbogbo... Totu masi pe ori eniyan se pataki ki pupo si isemi eda.. 

Ori lo nduro ti eniyan titi di Ojo iku (death) 

Ogun (charm) opada baje ni ojokan, tori re ni awon baba wa fima nse ipese fun ori, koda won tun ma nsise igbinyaju lati lefi dabobo (protect) ori kioma ba gba abode.... Kabiesi olodumare 🙏

Tori ti  awon ika eniyan  koba ni agbara lori elomiran, wonsima gba abode fun ori re koma ba rojutu oro aiye.... Olohun gbawa lowo abinu eni.. Amin 🙏


AWON NKAN WO LAMA NFIN NBO ORI...  

Ninu awon nkan tia lefi bo ori wa ni 👇

-Obi (kolanut) 

-orogbo (bitter-kola) 

-omi (water)

-igbin (snail) 

- agbon (coconut) 

-eja abori (catfish) 

Owo (money) 

Awon nkan ti opolopo eniyan ma tia ma fin nbo ori niyen... Awon nkan miran wa o tialefi bo ori wa tobaje pe iwadi lotoka si Awon nkan yen... Sugbon akin sadede lowon.. 


Gbogbo Awon nkan yi loni bi ase nlo won lati lefi bo ori wa... Sugbon iwadi nio so iru eyi toba kadara re mu.. 

(Mama gbe awon videos  jade laipe tiama soro Lori bi asele mafi Awon nkan yi bo ori wa) 


IRU ISEDA WO LORI BIBO SE PATAKI FUN JULO.. 


Opolopo eniyan lo ye kioma bo ori re sugbon anilo ori bibo yi ju arawa lo... 


- elomiran wa tojepe orire le(hard) gidigan.. Iru eniyan be kioma bo orire dada.. 


-Elomi wa tojepe orire tigba abode, onilo lati lobo orire.. 


-Iseda elomiran wa ni eyin re... Kio ma bo orire dada kiole ma ri ilosiwaju dada... 


-Elomiran tise Awon nkan totako irawo ati akosejaiye re, leyi tofa ti orire fin ntako... Kio se atunse irawo re kosi bo orire ki ona lebasi fun e.. 


AWON IRAWO KAN WA TOJEPE DANDAN NI ORI BIBO FUNWON.. 

Awon irawo yi le pupo, torire ni ori bibo fi se pataki fun won.. 

-IRAWO INA ( ARIES &LEO)

Die ni ti Sagittarius nibe sugbon onirawo Sagittarius ti ogun idile ba ndalaamu, ki ohun na yama bo orire kiwon maba gba abode fun iseda re.. 


IRAWO OMI (CANCER & SCORPIO) 

Awon iseda yi lagbara pupo tori iseda won le... Ogun idile asima damu Scorpio pupo leyi toni lati mabo orire dada... 

Die ni ti Pisces nibe, tikibasepe Awon ota gba abode fun iseda won... Sugbon Sara egbe lose pataki fun won 


-IRAWO AFEFE (GEMINI, LIBRA, AQUARIUS)

Pataki julo fun irawo MARIMIFIN (Libra) 


-IRAWO ERUPE (CAPRICORN, VIRGO)

Pataki julo fun irawo eruku( Capricorn) tori irawo Agba ni.. 



EWU ATI EWO TOWA LABE ORI BIBO..


-kodara ki afi oku eja (dead fish)  bo ori.. 

-Kodara  ki eniyan lasan bawa bo ori... 

-kodara ki aru eru(load)  si ori wa ni ojo ti aba bo ori wa tan... 

- kodara ki ama rin kakiri  ni ojo ti aba bo ori wa yita... 

- Ti onirawo omi tabi omo omi bafi eja bo ori, kodara ki won je eja abori yen.. Kiwon loju sinu odo (river) pada ni aye(live)... 

-Akin nbo ori losan ti abafe ri wahala leyin tiaba bo ori tan.. 

Kodara ki asi ori wa kale ti ababo ori wa laaro (ede fila white kan abi gele white) 


OJO ATI ASIKO TO DARA KIA BO ORI WA


-Asiko todara ju fun ori bibo ni aro kutukutu, ale tiafe sun tabi oru... 

-Ojo todara ju fun ori bibo ni ki eniyan  bo ori re ni ojo orire(lucky day) re.. 

Tobase iwadi irawo re wama ojo orire re .. 


Se iwadi irawo ati akosejaiye re kiole ma bi wase rin irin ajo aiye re... Opolopo eniyan lo nja ogun aiye lorisirisi... Sugbon koma iru ogun to nba e ja... Ayafi kiose iwadi irawo ati akosejaiye re 

Kiole ma ibi ti wahala ti wonu aiye re... 

Se ogun irawo lo nja eni abi asiri topama sinu akosejaiye re?...... 


Comments

Popular posts from this blog

IBASEPO AWON IRAWO(COMPATIBILITY OF STARS)

ÀJÉ (WEALTH)